14. Okuta wọnni si jasi gẹgẹ bi orukọ awọn ọmọ Israeli mejila, gẹgẹ bi orukọ wọn, bi ifin èdidi-àmi, olukuluku ti on ti orukọ rẹ̀, gẹgẹ bi ẹ̀ya mejejila.
15. Nwọn si ṣe ẹ̀wọn iṣẹ-ọnà-lilọ kìki wurà si igbàiya na.
16. Nwọn si ṣe oju-ìde wurà meji, ati oruka wurà meji; nwọn si fi oruka mejeji si eti igbàiya na mejeji.
17. Nwọn si fi ẹ̀wọn wurà iṣẹ-ọnà-lilọ mejeji bọ̀ inu oruka wọnni, ni eti igbàiya na.
18. Ati eti mejeji ti ẹ̀wọn iṣẹ-lilọ mejeji nì ni nwọn fi mọ́ inu oju-ìde mejeji, nwọn si fi wọn sara okùn ejika ẹ̀wu-efodi na niwaju rẹ̀.
19. Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si eti mejeji igbàiya na, si eti rẹ̀ ti o wà, ni ìha ẹ̀wu-efodi na ni ìha inu.
20. Nwọn si ṣe oruka wurà meji, nwọn si fi wọn si ìha mejeji ẹ̀wu-efodi na nisalẹ, si ìha iwaju rẹ̀, ki o kọjusi isolù rẹ̀, loke ọjá ẹ̀wu-efodi na.
21. Nwọn si fi oruka rẹ̀ dè igbàiya na mọ́ oruka ẹ̀wu-efodi pẹlu ọjá-àwọn aṣọ-aláró, ki o le ma wà lori onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi na, ati ki igbàiya ni ki o máṣe tú kuro lara ẹ̀wu-efodi na; bi OLUWA ti fi aṣẹ fun Mose.
22. O si ṣe aṣọ igunwa ẹ̀wu-efodi na ni iṣẹ wiwun, gbogbo rẹ̀ jẹ́ aṣọ-aláró.