Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 38:5-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. O si dà oruka mẹrin fun ìku mẹrẹrin àro idẹ na, li àye fun ọpá wọnni.

6. O si fi igi ṣittimu ṣe ọpá wọnni, o si fi idẹ bò wọn.

7. O si fi ọpá wọnni sinu oruka ni ìha pẹpẹ na, lati ma fi rù u; o fi apáko ṣe pẹpẹ na li onihò ninu.

8. O si fi idẹ ṣe agbada na, o si fi idẹ ṣe ẹsẹ̀ rẹ̀, ti awojiji ẹgbẹ awọn obinrin ti npejọ lati sìn li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

9. O si ṣe agbalá na: ni ìha gusù li ọwọ́ ọtún aṣọ-tita agbalá na jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ọgọrun igbọnwọ:

10. Opó wọn jẹ́ ogún, ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.

11. Ati fun ìha ariwa ọgọrun igbọnwọ, opó wọn jẹ́ ogún, ati ihò-ìtẹbọ idẹ wọn jẹ́ ogún; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.

12. Ati fun ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ, opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa; kọkọrọ opó wọnni ati ọjá wọn jẹ́ fadakà.

13. Ati fun ìha ìla-õrùn, si ìha ìla-õrùn ãdọta igbọnwọ.

14. Aṣọ-tita apakan jẹ́ igbọnwọ mẹdogun; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta.

15. Ati fun apa keji: li apa ihin ati li apa ọhún ẹnu-ọ̀na agbalá na, li aṣọ-tita onigbọnwọ mẹdogun wà; opó wọn jẹ́ mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn jẹ́ mẹta.

16. Gbogbo aṣọ-tita agbalá na yiká jẹ́ ọ̀gbọ olokùn wiwẹ.

Ka pipe ipin Eks 38