Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 31:3-11 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà.

4. Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ,

5. Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.

6. Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:

7. Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na.

8. Ati tabili na ati ohun-èlo rẹ̀, ati ọpá-fitila mimọ́ pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati pẹpẹ turari;

9. Ati pẹpẹ ẹbọ sisun pẹlu gbogbo ohunèlo rẹ̀, ati agbada nì ti on ti ẹsẹ̀ rẹ̀;

10. Ati aṣọ ìsin, ati aṣọ mimọ́ wọnni fun Aaroni alufa, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀, lati ma fi ṣe iṣẹ alufa;

11. Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe.

Ka pipe ipin Eks 31