Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 31:11-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Ati oróro itasori, ati turari olõrùn didùn fun ibi mimọ́ nì: gẹgẹ bi gbogbo eyiti mo palaṣẹ fun ọ ni nwọn o ṣe.

12. OLUWA si sọ fun Mose pe,

13. Ki iwọ ki o sọ fun awọn ọmọ Israeli pe, Ọjọ́ isimi mi li ẹnyin o pamọ́ nitõtọ: nitori àmi ni lãrin emi ati lãrin nyin lati irandiran nyin; ki ẹnyin ki o le mọ̀ pe emi li OLUWA ti o yà nyin simimọ́.

14. Nitorina ki ẹnyin ki o ma pa ọjọ́ isimi mọ́; nitoripe mimọ́ ni fun nyin: ẹniti o ba bà a jẹ́ on li a o pa nitõtọ: nitori ẹnikẹni ti o ba ṣe iṣẹkiṣẹ kan ninu rẹ̀, ọkàn na li a o ke kuro ninu awọn enia rẹ̀.

Ka pipe ipin Eks 31