Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 31:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. OLUWA si sọ fun Mose pe,

2. Wò ó, emi ti pè Besaleli li orukọ, ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀ya Judah:

3. Emi si fi ẹmi Ọlọrun kún u li ọgbọ́n, ati li oyé, ati ni ìmọ, ati li onirũru iṣẹ-ọnà.

4. Lati humọ̀ alarabara iṣẹ, lati ṣiṣẹ ni wurà, ati ni fadakà, ati ni idẹ,

5. Ati li okuta gbigbẹ lati tò wọn, ati ni igi fifin, lati ṣiṣẹ li onirũru iṣẹ-ọnà.

6. Ati emi, kiyesi i, mo fi Oholiabu, ọmọ Ahisamaki, ti ẹ̀ya Dani, pẹlu rẹ̀; ati ninu ọkàn awọn ti iṣe ọlọgbọ́n inu ni mo fi ọgbọ́n si, ki nwọn ki o le ma ṣe ohun gbogbo ti mo palaṣẹ fun ọ:

7. Agọ́ ajọ na, ati apoti ẹrí nì, ati itẹ́-ãnu ti o wà lori rẹ̀, ati gbogbo ohunèlo Agọ́ na.

Ka pipe ipin Eks 31