Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 29:25-36 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. Iwọ o si gbà wọn li ọwọ́ wọn, iwọ o si sun wọn lori pẹpẹ na li ẹbọ sisun, fun õrùn didùn niwaju OLUWA: ẹbọ ti a fi iná ṣe ni si OLUWA.

26. Iwọ o si mú igẹ̀ àgbo ìyasimimọ́ Aaroni, iwọ o si fì i li ẹbọ fifì niwaju OLUWA; ìpín tirẹ li eyinì.

27. Iwọ o si yà igẹ̀ ẹbọ fifì na simimọ́, ati itan ẹbọ agbesọsoke, ti a fì, ti a si gbesọsoke ninu àgbo ìyasimimọ́ na, ani ninu eyiti iṣe ti Aaroni, ati ninu eyiti iṣe ti awọn ọmọ rẹ̀:

28. Eyi ni yio si ma ṣe ti Aaroni ati ti awọn ọmọ rẹ̀ ni ìlana lailai lọwọ awọn ọmọ Israeli: nitori ẹbọ agbesọsoke ni: ẹbọ agbesọsoke ni yio si ṣe lati ọwọ́ awọn ọmọ Israeli, ninu ẹbọ alafia wọn, ani ẹbọ agbesọsoke wọn si OLUWA.

29. Ati aṣọ mimọ́ ti Aaroni ni yio ṣe ti awọn ọmọ rẹ̀ lẹhin rẹ̀, lati ma fi oróro yàn wọn ninu wọn, ati lati ma yà wọn simimọ́ ninu wọn.

30. Ẹnikan ninu awọn ọmọ rẹ̀ ti o ba jẹ́ alufa ni ipò rẹ̀ ni yio mú wọn wọ̀ ni ijọ́ meje, nigbati o ba wá sinu agọ́ ajọ, lati ṣe ìsin ni ibi mimọ́ nì.

31. Iwọ o si mú àgbo ìyasimimọ́ nì, iwọ o si bọ̀ ẹran rẹ̀ ni ibi mimọ́ kan.

32. Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si jẹ ẹran àgbo na, ati àkara na ti o wà ninu agbọ̀n nì, li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ.

33. Nwọn o si jẹ nkan wọnni ti a fi ṣètutu na, lati yà wọn simimọ́, ati lati sọ wọn di mimọ́: ṣugbọn alejò ni kò gbọdọ jẹ ninu rẹ̀, nitoripe mimọ́ ni.

34. Bi ohun kan ninu ẹran ìyasimimọ́ na, tabi ninu àkara na, ba kú titi di ojumọ́, nigbana ni ki iwọ ki o fi iná sun iyokù: a ki yio jẹ ẹ, nitoripe mimọ́ ni.

35. Bayi ni iwọ o si ṣe fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, gẹgẹ bi ohun gbogbo ti mo paṣẹ fun ọ: ijọ́ meje ni iwọ o fi yà wọn simimọ́.

36. Iwọ o si ma pa akọmalu kọkan li ojojumọ́ ṣe ẹbọ ẹ̀ṣẹ fun ètutu: iwọ o si wẹ̀ pẹpẹ na mọ́, nigbati iwọ ba ṣètutu si i tán, iwọ o si ta oróro si i lati yà a simimọ́.

Ka pipe ipin Eks 29