Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 29:12-24 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na.

13. Iwọ o si mú gbogbo ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bori ẹ̀dọ, ati ti iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, iwọ o si sun u lori pẹpẹ na.

14. Ṣugbọn ẹran akọmalu na, ati awọ rẹ̀, ati igbẹ rẹ̀, on ni ki iwọ ki o fi iná sun lẹhin ode ibudó: ẹbọ ẹ̀ṣẹ ni.

15. Iwọ o si mú àgbo kan; ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori.

16. Iwọ o si pa àgbo na, iwọ o si mú ẹ̀jẹ rẹ̀, iwọ o si fi i wọ́n pẹpẹ na yiká.

17. Iwọ o si kun àgbo na, iwọ o si fọ̀ ifun rẹ̀, ati itan rẹ̀, iwọ o si fi wọn lé ara wọn, ati lé ori rẹ̀.

18. Iwọ o si sun gbogbo àgbo na lori pẹpẹ na: ẹbọ sisun ni si OLUWA: õrùn didùn ni, ẹbọ ti a fi iná ṣe si OLUWA.

19. Iwọ o si mú àgbo keji; Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé àgbo na li ori.

20. Nigbana ni ki iwọ ki o pa àgbo na, ki o si mú ninu ẹ̀jẹ rẹ̀, ki o si tọ́ ọ si eti ọtún Aaroni, ati si eti ọtún awọn ọmọ rẹ̀, ati si àtampako ọwọ́ ọtún wọn, ati si àtampako ẹsẹ̀ ọtún wọn, ki o si fi ẹ̀jẹ na wọ́n pẹpẹ na yiká.

21. Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ ti o wà lori pẹpẹ, ati ninu oróro itasori, iwọ o si wọ́n ọ sara Aaroni, ati sara aṣọ rẹ̀, ati sara awọn ọmọ rẹ̀, ati sara aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀: ki a le sọ ọ di mimọ́, ati aṣọ rẹ̀, ati awọn ọmọ rẹ̀, ati aṣọ awọn ọmọ rẹ̀ pẹlu rẹ̀.

22. Iwọ o si mú ọrá, ati ìru ti o lọrá ti àgbo na, ati ọrá ti o bò ifun lori, ati àwọn ti o bò ẹ̀dọ̀, ati iwe mejeji, ati ọrá ti o wà lara wọn, ati itan ọtún; nitori àgbo ìyasimimọ́ ni:

23. Ati ìṣu àkara kan, ati àkara kan ti a fi oróro din, ati àkara fẹlẹfẹlẹ kan kuro ninu agbọ̀n àkara alaiwu, ti o wà niwaju OLUWA:

24. Iwọ o si fi gbogbo rẹ̀ lé Aaroni lọwọ, ati lé ọwọ́ awọn ọmọ rẹ̀; iwọ o si ma fì wọn li ẹbọ fifì niwaju OLUWA.

Ka pipe ipin Eks 29