Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 29:1-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EYI si li ohun ti iwọ o ṣe si wọn lati yà wọn simimọ́, lati ma ṣe alufa fun mi: mú ẹgbọ̀rọ akọmalu kan, ati àgbo meji ti kò li abùku.

2. Ati àkara alaiwu, ati adidùn àkara alaiwu ti a fi oróro pò, ati àkara fẹlẹfẹlẹ alaiwu ti a ta oróro si lori; iyẹfun alikama ni ki o fi ṣe wọn.

3. Iwọ o si fi wọn sinu agbọ̀n kan, iwọ o si mú wọn wá ninu agbọ̀n na, pẹlu akọmalu na ati àgbo mejeji.

4. Iwọ o si mú Aaroni pẹlu awọn ọmọ rẹ̀ wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, iwọ o si fi omi wẹ̀ wọn.

5. Iwọ o si mú aṣọ wọnni, iwọ o si fi ẹ̀wu-awọtẹlẹ nì wọ̀ Aaroni, ati aṣọ igunwa efodi, ati efodi, ati igbàiya, ki o si fi onirũru-ọnà ọjá ẹ̀wu-efodi dì i.

6. Iwọ o si fi fila nì dé e li ori, iwọ o si fi adé mimọ́ nì sara fila na.

7. Nigbana ni iwọ o si mú oróro itasori, iwọ o si dà a si i li ori, iwọ o si fi oróro yà a simimọ́.

8. Iwọ o si mú awọn ọmọ rẹ̀ wá tosi, iwọ o si wọ̀ wọn li ẹ̀wu.

9. Iwọ o si dì wọn li ọjá-amure, Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀, iwọ o si fi fila dé wọn: iṣẹ-alufa yio si ma jẹ́ ti wọn ni ìlana titi aiye: iwọ o si yà Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ simimọ́.

10. Iwọ o si mú akọmalu na wá siwaju agọ́ ajọ: ati Aaroni ati awọn ọmọ rẹ̀ yio si fi ọwọ́ wọn lé akọmalu na li ori.

11. Iwọ o si pa akọmalu na niwaju OLUWA, loju ọ̀na agọ́ ajọ.

12. Iwọ o si mú ninu ẹ̀jẹ akọmalu na, iwọ o si fi ika rẹ tọ́ ọ sara iwo pẹpẹ na; iwọ o si dà gbogbo ẹ̀jẹ na si ìha isalẹ pẹpẹ na.

Ka pipe ipin Eks 29