Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 27:12-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

12. Ati niti ibú agbalá na, ni ìha ìwọ-õrùn li aṣọ-tita ãdọta igbọnwọ yio wà: opó wọn mẹwa, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹwa.

13. Ati ibú agbalá na ni ìha ìla-õrùn si ìha ìla-õrùn yio jẹ́ ãdọta igbọnwọ.

14. Aṣọ-tita apakan ẹnu-ọ̀na na yio jẹ́ igbọnwọ mẹdogun: opó wọn mẹta, ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.

15. Ati ni ìha keji ni aṣọ-tita igbọnwọ mẹdogun yio wà: opó wọn mẹta, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹta.

16. Ati fun ẹnu-ọ̀na agbalá na aṣọ-tita ogún igbọnwọ yio wà, ti aṣọ-alaró, ati elesè-àluko, ati ododó, ati ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ti a fi iṣẹ abẹ́rẹ ṣe: opó wọn mẹrin, ati ihò-ìtẹbọ wọn mẹrin.

17. Gbogbo opó ti o yi sarè na ká li a o si fi ọpá fadakà sopọ̀; ikọ́ wọn yio jẹ́ fadakà, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.

18. Ìna agbalá na ki o jẹ́ ọgọrun igbọnwọ, ati ibú rẹ̀ arãdọtọta igbọnwọ, ati giga rẹ̀ igbọnwọ marun, ti ọ̀gbọ olokùn wiwẹ, ati ihò-ìtẹbọ wọn ti idẹ.

19. Gbogbo ohun-èlo agọ́ na, ni gbogbo ìsin rẹ̀, ati gbogbo ekàn rẹ̀, ati gbogbo ekàn agbalá na ki o jẹ́ idẹ.

20. Iwọ o si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki nwọn ki o mú oróro olifi daradara ti a gún fun ọ wá, fun imọlẹ, lati mu ki fitila ki o ma tàn nigbagbogbo.

21. Li agọ́ ajọ lẹhin ode aṣọ-ikele ti o wà niwaju ẹ̀rí na, Aaroni ti on ti awọn ọmọ rẹ̀ ni yio tọju rẹ̀ lati alẹ titi di owurọ̀ niwaju OLUWA: yio si di ìlana lailai ni irandiran wọn lọdọ awọn ọmọ Israeli.

Ka pipe ipin Eks 27