Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 18:7-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́.

8. Mose si sọ ohun gbogbo ti OLUWA ti ṣe si Farao, ati si awọn ara Egipti nitori Israeli fun ana rẹ̀, ati gbogbo ipọnju ti o bá wọn li ọ̀na, ati bi OLUWA ti gbà wọn.

9. Jetro si yọ̀ nitori gbogbo ore ti OLUWA ti ṣe fun Israeli, ẹniti o ti gbàla lọwọ awọn ara Egipti.

10. Jetro si wipe, Olubukún li OLUWA, ẹniti o gbà nyin là lọwọ awọn ara Egipti, ati lọwọ Farao, ẹniti o gbà awọn enia là lọwọ awọn ara Egipti.

11. Mo mọ̀ nisisiyi pe OLUWA tobi jù gbogbo oriṣa lọ: nitõtọ, ninu ọ̀ran ti nwọn ti ṣeféfe si wọn.

12. Jetro, ana Mose, si mù ẹbọ sisun, ati ẹbọ wá fun Ọlọrun: Aaroni si wá, ati gbogbo awọn àgba Israeli, lati bá ana Mose jẹun niwaju Ọlọrun.

13. O si ṣe ni ijọ́ keji ni Mose joko lati ma ṣe idajọ awọn enia: awọn enia si duro tì Mose lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ.

14. Nigbati ana Mose si ri gbogbo eyiti on nṣe fun awọn enia, o ni, Kili eyiti iwọ nṣe fun awọn enia yi? ẽṣe ti iwọ nikan fi dá joko, ti gbogbo enia si duro tì ọ, lati owurọ̀ titi o fi di aṣalẹ?

15. Mose si wi fun ana rẹ̀ pe, Nitoriti awọn enia ntọ̀ mi wá lati bère lọwọ Ọlọrun ni:

16. Nigbati nwọn ba li ẹjọ́, nwọn a tọ̀ mi wá; emi a si ṣe idajọ larin ẹnikini ati ẹnikeji, emi a si ma mú wọn mọ̀ ìlana Ọlọrun, ati ofin rẹ̀.

17. Ana Mose si wi fun u pe, Eyiti iwọ nṣe nì kò dara.

18. Dajudaju iwọ o dá ara rẹ lagara, ati iwọ, ati awọn enia yi ti o pẹlu rẹ: nitoriti nkan yi wuwo jù fun ọ; iwọ nikan ki yio le ṣe e tikalãrẹ.

19. Fetisilẹ nisisiyi si ohùn mi; emi o fun ọ ni ìmọ, Ọlọrun yio si pẹlu rẹ: iwọ wà niwaju Ọlọrun fun awọn enia yi, ki iwọ ki o ma mú ọ̀ran wọn wá si ọdọ Ọlọrun.

Ka pipe ipin Eks 18