1. NIGBATI Jetro, alufa Midiani, ana Mose, gbọ́ ohun gbogbo ti Ọlọrun ti ṣe fun Mose, ati fun Israeli awọn enia rẹ̀, ati pe, OLUWA mú Israeli lati Egipti jade wá;
2. Nigbana ni Jetro, ana Mose, mú Sippora aya Mose wá, lẹhin ti o ti rán a pada.
3. Ati awọn ọmọ rẹ̀ mejeji: ti orukọ ọkan njẹ Gerṣomu; nitoriti o wipe, Emi ṣe alejò ni ilẹ ajeji.
4. Ati orukọ ekeji ni Elieseri; nitoriti o wipe, Ọlọrun baba mi li alatilẹhin mi, o si gbà mi lọwọ idà Farao:
5. Ati Jetro, ana Mose, o tọ̀ Mose wá ti on ti awọn ọmọ rẹ̀, ati aya rẹ̀ si ijù, nibiti o gbé dó si lẹba oke Ọlọrun.
6. O si wi fun Mose pe, Emi Jetro ana rẹ li o tọ̀ ọ wá, pẹlu aya rẹ, ati awọn ọmọ rẹ mejeji pẹlu rẹ̀.
7. Mose si jade lọ ipade ana rẹ̀, o si tẹriba, o si fi ẹnu kò o li ẹnu, nwọn si bére alafia ara wọn; nwọn si wọ̀ inu agọ́.