Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Eks 1:7-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

7. Awọn ọmọ Israeli si bisi i, nwọn si pọ̀si i gidigidi, nwọn si rẹ̀, nwọn si di alagbara nla jọjọ; ilẹ na si kún fun wọn.

8. Ọba titun miran si wa ijẹ ni Egipti, ti kò mọ́ Josefu.

9. O si wi fun awọn enia rẹ̀ pe, kiye si i, enia awọn ọmọ Israeli npọ̀, nwọn si nlagbara jù wa lọ:

10. Ẹ wá na, ẹ jẹ ki a fi ọgbọ́n ba wọn ṣe; ki nwọn ki o máṣe bisi i, yio si ṣe nigbati ogun kan ba ṣẹ̀, nwọn o dàpọ mọ́ awọn ọtá wa pẹlu, nwọn o ma bá wa jà, nwọn o si jade kuro ni ilẹ yi.

11. Nitorina ni nwọn ṣe yàn akoniṣiṣẹ le wọn, lati fi iṣẹ wọn pọ́n wọn loju. Nwọn si kọ́ ilu iṣura fun Farao, Pitomu ati Ramesesi.

12. Bi nwọn si ti npọ́n wọn loju si i, bẹ̃ni nwọn mbisi i, ti nwọn si npọ̀. Inu wọn si bàjẹ́ nitori awọn ọmọ Israeli.

13. Awọn ara Egipti si mu awọn ọmọ Israeli sìn li asìnpa:

14. Nwọn si fi ìsin lile, li erupẹ ati ni briki ṣiṣe, ati ni oniruru ìsin li oko mu aiye wọn korò: gbogbo ìsin wọn ti nwọn mu wọn sìn, asìnpa ni.

Ka pipe ipin Eks 1