Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 4:13-22 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nitori ẹ̀ṣẹ awọn woli rẹ̀, ati aiṣedede awọn alufa rẹ̀, ti nwọn ti ta ẹ̀jẹ awọn olododo silẹ li ãrin rẹ̀.

14. Nwọn ti rin kiri bi afọju ni ita, nwọn di alaimọ́ fun ẹ̀jẹ tobẹ̃ ti enia kò le fi ọwọ kan aṣọ wọn.

15. Nwọn nkigbe si wọn pe, ẹ lọ! alaimọ́ ni! ẹ lọ! ẹ lọ! ẹ máṣe fi ọwọ kan a! nigbati nwọn salọ, nwọn si rìn kiri pẹlu: nwọn nwi lãrin awọn orilẹ-ède pe, awọn kì o ṣatipo nibẹ mọ.

16. Oju Oluwa ti tú wọn ka: on kì o fiyesi wọn mọ: nwọn kò buyin fun awọn alufa, nwọn kò ṣãnu fun awọn àgbagba.

17. Bi o ṣe ti wa ni, oju wa nwọ̀na siwaju ati siwaju, fun iranlọwọ wa ti o jẹ asan: lori ile-iṣọ wa, awa nwọ̀na fun orilẹ-ède, ti kò le ràn ni lọwọ.

18. Nwọn dẹkun si ipa ọ̀na wa, ti awa kò le rìn ita wa: opin wa sunmọ tosi, ọjọ wa pé; nitori opin wa de.

19. Awọn ti nlepa wa yara jù idì ọrun lọ: nwọn nlepa wa lori oke wọnni, nwọn bà dè wa li aginju.

20. Ẽmi iho imu wa, ani ẹni-ororo Oluwa, ni a mu ninu ọ̀fin wọn, niti ẹniti awa wipe, labẹ ojiji rẹ̀ li awa o ma gbé lãrin awọn orilẹ-ède.

21. Yọ̀, ki inu rẹ si dùn, iwọ ọmọbinrin Edomu, ti ngbe inu ilẹ Usi; sibẹ ago na yio kọja sọdọ rẹ pẹlu: iwọ o si yo bi ọ̀muti, a o si tu ọ ni ihoho.

22. A mu aiṣedede rẹ kuro, iwọ ọmọbinrin Sioni: on kì o si tun mu ọ lọ si igbekun mọ: On o bẹ̀ aiṣedede rẹ wò, iwọ ọmọbinrin Edomu; yio si fi ẹ̀ṣẹ rẹ hàn.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 4