Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 3:49-63 Yorùbá Bibeli (YCE)

49. Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi.

50. Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá,

51. Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi.

52. Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi.

53. Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi.

54. Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe!

55. Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá.

56. Iwọ ti gbọ́ ohùn mi: máṣe se eti rẹ mọ si imikanlẹ mi, si igbe mi.

57. Iwọ sunmọ itosi li ọjọ ti emi kigbe pè ọ: iwọ wipe: Má bẹ̀ru!

58. Oluwa, iwọ ti gba ijà mi jà; iwọ ti rà ẹmi mi pada.

59. Oluwa, iwọ ti ri inilara mi, ṣe idajọ ọran mi!

60. Iwọ ti ri gbogbo igbẹsan wọn, gbogbo èro buburu wọn si mi.

61. Iwọ ti gbọ́ ẹ̀gan wọn, Oluwa, gbogbo èro buburu wọn si mi.

62. Ète awọn wọnni ti o dide si mi, ati ipinnu wọn si mi ni gbogbo ọjọ.

63. Kiyesi ijoko wọn ati idide wọn! emi ni orin-ẹsin wọn.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 3