Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 3:46-55 Yorùbá Bibeli (YCE)

46. Gbogbo awọn ọta wa ti ya ẹnu wọn si wa.

47. Ẹ̀ru ati ọ̀fin wá sori wa, idahoro ati iparun.

48. Oju mi fi odò omi ṣan silẹ, nitori iparun ọmọbinrin awọn enia mi.

49. Oju mi dà silẹ ni omije, kò si dá, laiṣe isimi.

50. Titi Oluwa fi wò ilẹ, ti o wò lati ọrun wá,

51. Oju mi npọn ọkàn mi loju, nitori gbogbo awọn ọmọbinrin ilu mi.

52. Awọn ọta mi dẹkùn fun mi gidigidi, gẹgẹ bi fun ẹiyẹ laini idi.

53. Nwọn ti ke ẹmi mi kuro ninu iho, nwọn si yi okuta sori mi.

54. Nwọn mu omi ṣan lori mi; emi wipe, Mo gbe!

55. Emi kepe orukọ rẹ, Oluwa, lati iho jijin wá.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 3