4. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi.
5. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka.
6. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.
7. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo
8. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ.
9. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po.
10. On jẹ bi ẹranko beari ti o ba dè mi, bi kiniun ni ibi ìkọkọ.
11. O ti mu mi ṣina li ọ̀na mi, o si fà mi ya pẹrẹpẹrẹ: o ti sọ mi di ahoro.
12. O ti fà ọrun rẹ̀, o si fi mi ṣe itasi fun ọfa rẹ̀.
13. O ti mu ki ọfà apó rẹ̀ wọ inu-ẹdọ mi lọ.
14. Emi jẹ ẹni ẹsin fun gbogbo enia mi; orin wọn ni gbogbo ọjọ.
15. O ti fi ìkoro mu mi yo, o ti mu mi mu omi wahala.