Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 3:33-43 Yorùbá Bibeli (YCE)

33. Nitori on kì ifẹ ipọn-ni-loju lati ọkàn rẹ̀ wá, bẹ̃ni kì ibà ọmọ enia ninu jẹ.

34. Lati tẹ̀ gbogbo ara-tubu ilẹ-aiye mọlẹ li abẹ ẹsẹ rẹ̀.

35. Lati yi ẹ̀tọ enia sapakan niwaju Ọga-ogo julọ.

36. Lati yi ọ̀ran idajọ enia pada, Oluwa kò fẹ ri i?

37. Tali ẹniti iwi, ti isi iṣẹ, nigbati Oluwa kò paṣẹ rẹ̀.

38. Ibi ati rere kò ha njade lati ẹnu Ọga-ogo-julọ wá?

39. Ẽṣe ti enia alãye nkùn? ti o wà lãye, ki olukuluku ki o kùn nitori ẹ̀ṣẹ rẹ̀!

40. Jẹ ki a wádi, ki a si dán ọ̀na wa wò, ki a si tun yipada si Oluwa.

41. Jẹ ki a gbe ọkàn ati ọwọ wa soke si Ọlọrun li ọrun.

42. Awa ti dẹṣẹ, a si ti ṣọtẹ: iwọ kò ti dariji.

43. Iwọ ti fi ibinu bora, o si ṣe inunibini si wa: iwọ ti pa, o kò si ti dasi.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 3