Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 3:18-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Emi si wipe, Agbara mi ati ireti mi ṣègbe kuro lọdọ Oluwa.

19. Ranti wahala mi ati inilara mi, ani ìkoro ati orõro.

20. Lõtọ, nigbati ọkàn mi nṣe iranti wọn, o si tẹriba ninu mi.

21. Eyi ni emi o rò li ọkàn mi, nitorina emi o ma reti.

22. Ãnu Oluwa ni, ti awa kò parun tan, nitori irọnu-ãnu rẹ kò li opin.

23. Ọtun ni li orowurọ; titobi ni otitọ rẹ.

24. Oluwa ni ipin mi, bẹ̃li ọkàn mi wi; nitorina ni emi ṣe reti ninu rẹ̀.

25. Oluwa ṣe rere fun gbogbo ẹniti o duro dè e, fun ọkàn ti o ṣafẹri rẹ̀.

26. O dara ti a ba mã reti ni idakẹjẹ fun igbala Oluwa.

27. O dara fun ọkunrin, ki o gbe àjaga ni igba-ewe rẹ̀.

28. Ki o joko on nikan, ki o si dakẹ, nitori Ọlọrun ti gbe e le ori rẹ̀.

29. Ki o fi ẹnu rẹ̀ sinu ẽkuru; pe bọya ireti le wà:

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 3