Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Ẹk. Jer 3:1-9 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. EMI ni ọkunrin na ti o ti ri wàhala nipa ọpa ibinu rẹ̀.

2. O ti fà mi, o si mu mi wá sinu òkunkun, kì si iṣe sinu imọlẹ.

3. Lõtọ, o yi ọwọ rẹ̀ pada si mi siwaju ati siwaju li ọjọ gbogbo.

4. O ti sọ ẹran-ara mi ati àwọ mi di ogbó, o ti fọ́ egungun mi.

5. O ti mọdi tì mi, o fi orõrò ati ãrẹ̀ yi mi ka.

6. O ti fi mi si ibi òkunkun, bi awọn ti o ti kú pẹ.

7. O ti sọgba yi mi ka, ti emi kò le jade; o ti ṣe ẹ̀wọn mi wuwo

8. Bi emi ti kigbe pẹlu, ti emi si npariwo, o sé adura mi mọ.

9. O ti fi okuta gbigbẹ sọgba yi ọ̀na mi ka, o ti yi ipa ọ̀na mi po.

Ka pipe ipin Ẹk. Jer 3