Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 6:11-18 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀.

12. Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada.

13. Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.

14. Nigbati ọba gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, inu rẹ̀ bajẹ gidigidi o si fi ọkàn rẹ̀ si Danieli lati gbà a silẹ: o si ṣe lãlã ati gbà a silẹ titi fi di igbati õrun wọ̀.

15. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi pejọ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi fun ọba pe, Iwọ mọ̀, ọba, pe ofin awọn ara Media ati Persia ni pe: kò si aṣẹ tabi ofin ti ọba fi lelẹ ti a gbọdọ yipada.

16. Nigbana ni ọba paṣẹ, nwọn si mu Danieli wá, nwọn si gbé e sọ sinu iho kiniun. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Ọlọrun rẹ, ẹniti iwọ nsìn laisimi, on o gbà ọ la.

17. A si yi okuta kan wá, nwọn si gbé e ka oju iho na; ọba si fi oruka edidi rẹ̀ sami si i, ati oruka edidi awọn ijoye rẹ̀, ki ohunkohun máṣe yipada nitori Danieli.

18. Nigbana ni Ọba wọ̀ ãfin rẹ̀ lọ, o si fi oru na gbàwẹ: bẹ̃li a kò si gbé ohun-elo orin kan wá siwaju rẹ̀: orun kò si wá si oju rẹ̀.

Ka pipe ipin Dan 6