Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 5:27-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

27. TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to.

28. PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia.

29. Nigbana ni Belṣassari paṣẹ, nwọn si wọ̀ Danieli li aṣọ ododó, a si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a si ṣe ikede niwaju rẹ̀ pe, ki a fi i ṣe olori ẹkẹta ni ijọba.

30. Loru ijọ kanna li a pa Belṣassari, ọba awọn ara Kaldea.

31. Dariusi, ara Media si gba ijọba na, o si jẹ bi ẹni iwọn ọdun mejilelọgọta.

Ka pipe ipin Dan 5