Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 5:14-27 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ,

15. Njẹ nisisiyi, a ti mu awọn amoye, ati awọn ọlọgbọ́n wá siwaju mi, ki nwọn ki o le ka iwe yi, ati lati fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn nwọn kò le fi itumọ ọ̀ran na hàn:

16. Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba.

17. Nigbana ni Danieli dahùn, o si wi niwaju ọba pe, Jẹ ki ẹ̀bun rẹ gbe ọwọ rẹ, ki o si fi ẹsan rẹ fun ẹlomiran; ṣugbọn emi o ka iwe na fun ọba, emi o si fi itumọ rẹ̀ hàn fun u.

18. Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ:

19. Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ.

20. Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀:

21. A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀.

22. Ati iwọ Belṣassari, ọmọ rẹ̀, iwọ kò rẹ̀ ọkàn rẹ silẹ, bi iwọ si tilẹ ti mọ̀ gbogbo nkan wọnyi;

23. Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun.

24. Nitorina ni a ṣe rán ọwọ na lati ọdọ rẹ̀ wá; ti a si fi kọ iwe yi.

25. Eyiyi si ni iwe na ti a kọ, MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.

26. Eyi ni itumọ ohun na: MENE, Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rẹ̀.

27. TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to.

Ka pipe ipin Dan 5