Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 5:13-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. Nigbana ni a mu Danieli wá siwaju ọba. Ọba si dahùn o wi fun Danieli pe, Iwọ ni Danieli nì, ti iṣe ti inu awọn ọmọ igbekun Juda! awọn ẹniti ọba, baba mi kó lati ilẹ Juda wá?

14. Emi ti gburo rẹ pe ẹmi Ọlọrun mbẹ lara rẹ, ati pe, a ri imọlẹ, ati oye, ati ọgbọ́n titayọ lara rẹ,

15. Njẹ nisisiyi, a ti mu awọn amoye, ati awọn ọlọgbọ́n wá siwaju mi, ki nwọn ki o le ka iwe yi, ati lati fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn nwọn kò le fi itumọ ọ̀ran na hàn:

16. Emi si gburo rẹ pe, iwọ le ṣe itumọ, iwọ si le tu ọ̀rọ ti o diju: njẹ nisisiyi, bi iwọ ba le ka iwe na, ti iwọ ba si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, a o wọ̀ ọ li aṣọ ododó, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ́ ọ lọrun, a o si fi ọ jẹ olori ẹkẹta ni ijọba.

17. Nigbana ni Danieli dahùn, o si wi niwaju ọba pe, Jẹ ki ẹ̀bun rẹ gbe ọwọ rẹ, ki o si fi ẹsan rẹ fun ẹlomiran; ṣugbọn emi o ka iwe na fun ọba, emi o si fi itumọ rẹ̀ hàn fun u.

18. Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ:

19. Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ.

20. Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀:

Ka pipe ipin Dan 5