Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 5:1-7 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. BELṢASSARI, ọba se àse nla fun ẹgbẹrun awọn ijoye rẹ̀, o si nmu ọti-waini niwaju awọn ẹgbẹrun na.

2. Bi Belṣassari ti tọ́ ọti-waini na wò, o paṣẹ pe ki nwọn ki o mu ohun-elo wura, ati ti fadaka wá, eyiti Nebukadnessari baba rẹ̀, kó jade lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu wá, ki ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, ki o le ma muti ninu wọn.

3. Nigbana ni nwọn mu ohun-elo wura ti a ti kó jade lati inu tempili ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu wá; ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, si nmuti ninu wọn.

4. Nwọn nmu ọti-waini, nwọn si nkọrin ìyin si awọn oriṣa wura, ati ti fadaka, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta.

5. Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na.

6. Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn.

7. Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba.

Ka pipe ipin Dan 5