Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Dan 11:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU li ọdun kini Dariusi ara Media, emi pãpa duro lati mu u lọkàn le, ati lati fi idi rẹ̀ kalẹ.

2. Njẹ nisisiyi li emi o fi otitọ hàn ọ, Kiyesi i, ọba mẹta pẹlu ni yio dide ni Persia; ẹkẹrin yio si ṣe ọlọrọ̀ jù gbogbo wọn lọ: ati nipa agbara rẹ̀ ni yio fi fi ọrọ̀ rú gbogbo wọn soke si ijọba Hellene.

3. Ọba alagbara kan yio si dide, yio si fi agbara nla ṣe akoso, yio si ma ṣe gẹgẹ bi ifẹ inu rẹ̀.

4. Nigbati on ba dide tan, ijọba rẹ̀ yio fọ́, a o si pin i si orígun mẹrẹrin ọrun; kì si iṣe fun ọmọ rẹ̀, pẹlupẹlu kì si iṣe ninu agbara rẹ̀ ti on fi jọba, nitoriti a o fa ijọba rẹ̀ tu, ani fun ẹlomiran lẹhin awọn wọnyi.

5. Ọba iha gusu yio si lagbara; ṣugbọn ọkan ninu awọn balogun rẹ̀, on o si lagbara jù u lọ, yio si jọba, ijọba rẹ̀ yio jẹ ijọba nla.

6. Lẹhin ọdun pipọ nwọn o si kó ara wọn jọ pọ̀; ọmọbinrin ọba gusu yio wá sọdọ ọba ariwa, lati ba a dá majẹmu: ṣugbọn on kì yio le di agbara apá na mu; bẹ̃ni on kì yio le duro, tabi apá rẹ̀: ṣugbọn a o fi on silẹ, ati awọn ti o mu u wá, ati ẹni ti o bi i, ati ẹniti nmu u lọkàn le li akokò ti o kọja.

7. Ṣugbọn ninu ẹka gbòngbo rẹ̀ li ẹnikan yio dide ni ipò rẹ̀, ẹniti yio wá pẹlu ogun, yio si wọ̀ ilu-olodi ọba ariwa, yio si ba wọn ṣe, yio si bori.

8. On o si kó oriṣa wọn pẹlu ere didà wọn, ati ohunelo wọn daradara, ti fadaka, ati ti wura ni igbekun lọ si Egipti; on o si duro li ọdun melokan kuro lọdọ ọba ariwa.

9. On o si lọ si ijọba ọba gusu, ṣugbọn yio yipada si ilẹ ontikararẹ̀.

10. Ṣugbọn awọn ọmọ rẹ̀ yio ru soke, nwọn o si gbá ogun nla ọ̀pọlọpọ enia jọ; ẹnikan yio wọle wá, yio si bolẹ̀, yio si kọja lọ. Nigbana ni yio pada yio si gbé ogun lọ si ilu olodi rẹ̀.

Ka pipe ipin Dan 11