Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amo 1:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Edomu, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori o fi idà lepa arakunrin rẹ̀, o si gbe gbogbo ãnu sọnù; ibinu rẹ̀ si nfaniya titi, o si pa ibinu rẹ̀ mọ titi lai.

12. Ṣugbọn emi o rán iná kan si Temani, ti yio jó afin Bosra wọnni run.

13. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti awọn ọmọ Ammoni, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti là inu awọn aboyun Gileadi, ki nwọn le ba mu agbègbe wọn tobi:

14. Ṣugbọn emi o da iná kan ninu odi Rabba, yio si jó ãfin rẹ̀ wọnni run, pẹlu iho ayọ̀ li ọjọ ogun, pẹlu ijì li ọjọ ãjà:

15. Ọba wọn o si lọ si igbèkun, on ati awọn ọmọ-alade rẹ̀ pọ̀, li Oluwa wi.

Ka pipe ipin Amo 1