Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Amo 1:1-10 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. Ọ̀RỌ Amosi, ẹniti o wà ninu awọn darandaran Tekoa, ti o ri niti Israeli li ọjọ ọba Ussiah ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli, ọdun meji ṣãju isẹ̀lẹ nì.

2. O si wipe, Oluwa yio bu jade lati Sioni wá, yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ lati Jerusalemu wá; ibùgbe awọn olùṣọ-agùtan yio si ṣọ̀fọ, oke Karmeli yio si rọ.

3. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi:

4. Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run.

5. Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.

6. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Gasa, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti kó gbogbo igbèkun ni igbèkun lọ, lati fi wọn le Edomu lọwọ.

7. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Gasa, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run:

8. Emi o si ke ara Aṣdodi kuro, ati ẹniti o di ọpá alade mu kuro ni Aṣkeloni, emi o si yi ọwọ́ mi si Ekroni; iyokù ninu awọn ara Filistia yio ṣegbe, li Oluwa Ọlọrun wi.

9. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Tire, ati nitori mẹrin: emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn fi gbogbo igbèkun le Edomu lọwọ, nwọn kò si ranti majẹmu arakunrin.

10. Ṣugbọn emi o rán iná kan sara odi Tire, ti yio jo ãfin rẹ̀ wọnni run.

Ka pipe ipin Amo 1