Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

A. Oni 21:20-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

20. Nwọn si fi aṣẹ fun awọn ọmọ Benjamini wipe, Ẹ lọ ki ẹ si ba sinu ọgbà-àjara;

21. Ki ẹ si wò, si kiyesi i, bi awọn ọmọbinrin Ṣilo ba jade wá lati jó ninu ijó wọnni, nigbana ni ki ẹnyin ki o jade lati inu ọgbà-àjara wá, ki olukuluku ọkunrin nyin ki o si mú aya rẹ̀ ninu awọn ọmọbinrin Ṣilo, ki ẹnyin ki o si lọ si ilẹ Benjamini.

22. Yio si ṣe, nigbati awọn baba wọn tabi awọn arakunrin wọn ba tọ̀ wa wá lati wijọ, awa o si wi fun wọn pe, Ẹ ṣãnu wọn nitori wa: nitoriti awa kò mú aya olukuluku fun u li ogun na: bẹ̃ni ki iṣe ẹnyin li o fi wọn fun wọn; nigbana ni ẹnyin iba jẹbi.

23. Awọn ọmọ Benjamini si ṣe bẹ̃, nwọn si mú aya, gẹgẹ bi iye wọn, ninu awọn ẹniti njó, awọn ti nwọn múlọ; nwọn si lọ nwọn pada si ilẹ-iní wọn nwọn si kọ ilu wọnni, nwọn si joko sinu wọn.

24. Nigbana li awọn ọmọ Israeli si lọ lati ibẹ̀, olukuluku enia si ẹ̀ya tirẹ̀, ati si idile tirẹ̀, nwọn si jade lati ibẹ̀ lọ olukuluku enia si ilẹ-iní tirẹ̀.

25. Li ọjọ́ wọnni ọba kan kò sí ni Israeli: olukuluku nṣe eyiti o tọ́ li oju ara rẹ̀.

Ka pipe ipin A. Oni 21