Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

A. Oni 21:11-16 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Eyiyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: gbogbo ọkunrin, ati gbogbo obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin li ẹnyin o parun patapata.

12. Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani.

13. Gbogbo ijọ si ranṣẹ lọ bá awọn ọmọ Benjamini ti o wà ninu okuta Rimmoni sọ̀rọ, nwọn si fi alafia lọ̀ wọn.

14. Benjamini si pada li akokò na; nwọn si fun wọn li obinrin ti nwọn dasi ninu awọn obinrin Jabeṣi-gileadi: ṣugbọn sibẹ̀ nwọn kò si kari wọn.

15. Awọn enia na si kãnu nitori Benjamini, nitoripe OLUWA ṣe àlàfo ninu awọn ẹ̀ya Israeli.

16. Nigbana li awọn àgba ijọ wipe, Kini awa o ṣe niti obinrin fun awọn iyokù, nitoripe a ti pa gbogbo awọn obinrin run kuro ni Benjamini?

Ka pipe ipin A. Oni 21