Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

A. Oni 21:1-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AWỌN ọkunrin Israeli si ti bura ni Mispe, pe, Ẹnikan ninu wa ki yio fi ọmọbinrin rẹ̀ fun Benjamini li aya.

2. Awọn enia na si wá si Beti-eli, nwọn si joko nibẹ̀ titi di aṣalẹ niwaju Ọlọrun, nwọn si gbé ohùn wọn soke, nwọn si sọkun gidigidi.

3. Nwọn si wipe, OLUWA, Ọlọrun Israeli, ẽṣe ti o fi ri bayi ni Israeli, ti ẹ̀ya kan fi bùku li oni ninu awọn enia Israeli?

4. O si ṣe ni ijọ́ keji, awọn enia na dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si mọ pẹpẹ kan nibẹ̀, nwọn si ru ẹbọ sisun, ati ẹbọ alafia.

5. Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a.

6. Awọn ọmọ Israeli si kãnu nitori Benjamini arakunrin wọn, nwọn si wipe, A ke ẹ̀ya kan kuro ni Israeli li oni.

7. Awa o ha ti ṣe niti obinrin fun awọn ti o kù, awa sá ti fi OLUWA bura pe, awa ki yio fi awọn ọmọbinrin wa fun wọn li aya.

8. Nwọn si wipe, Ewo ni ninu awọn ẹ̀ya Israeli ti kò tọ̀ OLUWA wá ni Mispe? Si kiyesi i, kò sí ẹnikan ni ibudó ti o ti Jabeṣi-gileadi wá si ijọ.

9. Nitori nigbati a kà awọn enia na, si kiyesi i, kò sí ẹnikan nibẹ̀ ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi.

10. Ijọ si rán ẹgbã mẹfa ọkunrin ninu awọn akọni sibẹ̀, nwọn si fi aṣẹ fun wọn pe, Ẹ lọ ẹ si fi oju idà kọlù awọn ara Jabeṣi-gileadi, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọ wẹrẹ.

11. Eyiyi ni nkan ti ẹnyin o ṣe: gbogbo ọkunrin, ati gbogbo obinrin ti o ti mọ̀ ọkunrin li ẹnyin o parun patapata.

12. Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani.

13. Gbogbo ijọ si ranṣẹ lọ bá awọn ọmọ Benjamini ti o wà ninu okuta Rimmoni sọ̀rọ, nwọn si fi alafia lọ̀ wọn.

14. Benjamini si pada li akokò na; nwọn si fun wọn li obinrin ti nwọn dasi ninu awọn obinrin Jabeṣi-gileadi: ṣugbọn sibẹ̀ nwọn kò si kari wọn.

Ka pipe ipin A. Oni 21