Nwọn si wi fun u pe, Rárá o; didè li awa o dè ọ, a o si fi ọ lé wọn lọwọ: ṣugbọn niti pipa awa ki yio pa ọ. Nwọn si fi okùn titun meji dè e, nwọn si mú u gòke lati ibi apata na wá.