Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

A. Oni 1:25-35 Yorùbá Bibeli (YCE)

25. O si fi ọ̀na atiwọ̀ ilu na hàn wọn, nwọn si fi oju idà kọlù ilu na; ṣugbọn nwọn jọwọ ọkunrin na ati gbogbo awọn ara ile rẹ̀ lọwọ lọ.

26. Ọkunrin na si lọ si ilẹ awọn Hitti, o si tẹ̀ ilu kan dó, o si pè orukọ rẹ̀ ni Lusi: eyi si li orukọ rẹ̀ titi di oni.

27. Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na.

28. O si ṣe, nigbati Israeli di alagbara tán, nwọn si mu awọn ara Kenaani sìn, nwọn kò si lé wọn jade patapata.

29. Efraimu kò si lé awọn ara Kenaani ti ngbé Geseri jade; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn ni Geseri.

30. Sebuluni kò lé awọn ara Kitroni jade, tabi awọn ara Nahalolu; ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ãrin wọn, nwọn si nsìn.

31. Aṣeri kò lé awọn ara Akko jade, tabi awọn ara Sidoni, tabi awọn ara Alabu, tabi awọn ara Aksibu, tabi awọn ara Helba, tabi awọn ara Afiki, tabi awọn ara Rehobu:

32. Ṣugbọn awọn ọmọ Aṣeri ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: nitoriti nwọn kò lé wọn jade.

33. Naftali kò lé awọn ara Beti-ṣemeṣi jade, tabi awọn ara Beti-anati; ṣugbọn on ngbé ãrin awọn ara Kenaani, ti ngbé ilẹ na: ṣugbọn awọn ara Beti-ṣemeṣi ati Beti-anati di ẹniti nsìn wọn.

34. Awọn Amori si fi agbara tì awọn ọmọ Dani sori òke: nitoripe nwọn kò jẹ ki nwọn ki o sọkalẹ wá si afonifoji.

35. Awọn Amori si ngbé òke Heresi, ni Aijaloni, ati ni Ṣaalbimu: ọwọ́ awọn ara ile Josefu bori, nwọn si di ẹniti nsìn.

Ka pipe ipin A. Oni 1