Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Titu 3:7-15 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Ó dá wa láre nípa oore-ọ̀fẹ́ kan náà, tí a fi ní ìrètí láti di ajogún ìyè ainipẹkun.

8. Ọ̀rọ̀ tí ó dájú ni ọ̀rọ̀ yìí.Mo fẹ́ kí o tẹnumọ́ àwọn nǹkan wọnyi, kí àwọn tí ó ti gba Ọlọrun gbọ́ lè fi ọkàn sí i láti máa ṣe iṣẹ́ tí ó dára. Irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ dára, wọ́n sì ń ṣe eniyan ní anfaani.

9. Ṣugbọn yẹra fún iyàn jíjà lórí ọ̀rọ̀ wèrè ati ìtàn ìrandíran, ati ìjà, ati àríyànjiyàn lórí ọ̀rọ̀ òfin. Nítorí wọn kò ṣe eniyan ní anfaani, wọn kò sì wúlò rárá.

10. Bí o bá ti kìlọ̀ fún adíjàsílẹ̀ lẹ́ẹ̀kan tabi lẹẹmeji, tí kò gbọ́, yẹra fún un.

11. Mọ̀ pé ọkàn irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti wọ́, ó ń dá ẹ̀ṣẹ̀, ó sì ń dá ara rẹ̀ lẹ́bi.

12. Nígbà tí mo bá rán Atemasi tabi Tukikọsi sí ọ, sa ipá rẹ láti wá sọ́dọ̀ mi ní ìlú Nikopoli, nítorí níbẹ̀ ni mo pinnu láti wà ní àkókò òtútù.

13. Sa gbogbo ipá rẹ láti ran Senasi, lọ́yà, ati Apolo lọ́wọ́ kí wọn lè bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, kí o sì rí i pé gbogbo ohun tí wọ́n nílò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́.

14. Àwọn eniyan wa níláti kọ́ láti ṣe iṣẹ́ rere kí wọ́n lè gbọ́ bùkátà wọn; wọn kò gbọdọ̀ jókòó tẹtẹrẹ láìṣe nǹkankan.

15. Gbogbo àwọn ẹni tí ó wà lọ́dọ̀ mi ní kí n kí ọ. Bá wa kí gbogbo àwọn ọ̀rẹ́ wa ninu igbagbọ.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín.

Ka pipe ipin Titu 3