Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 4:4-14 BIBELI MIMỌ (BM)

4. Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́,

5. nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́.

6. Bí o bá ń fi irú ọ̀rọ̀ báyìí siwaju àwọn arakunrin, ìwọ yóo jẹ́ òjíṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a tọ́ dàgbà ninu ọ̀rọ̀ igbagbọ ati ẹ̀kọ́ rere tí ò ń tẹ̀lé.

7. Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun.

8. Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀.

9. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn.

10. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.

11. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan.

12. Má jẹ́ kí ẹnikẹ́ni kẹ́gàn rẹ, nítorí pé o jẹ́ ọ̀dọ́. Ṣugbọn jẹ́ àpẹẹrẹ fún àwọn onigbagbọ ninu ọ̀rọ̀ rẹ, ati ninu ìṣe rẹ, ninu ìfẹ́, ninu igbagbọ ati ninu ìwà pípé.

13. Kí n tó dé, tẹra mọ́ kíka ọ̀rọ̀ Ọlọrun, ati gbígba àwọn eniyan níyànjú, ati iṣẹ́ olùkọ́ni.

14. Má ṣe àìnáání ẹ̀bùn tí Ẹ̀mí Mímọ́ fún ọ nípa àsọtẹ́lẹ̀ nígbà tí àwọn àgbà ìjọ gbé ọwọ́ lé ọ lórí.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 4