Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Kinni 4:1-11 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ẹ̀mí sọ pàtó pé nígbà tí ó bá yá, àwọn ẹlòmíràn yóo yapa kúrò ninu ẹ̀sìn igbagbọ, wọn yóo tẹ̀lé àwọn ẹ̀mí ẹ̀tàn ati ẹ̀kọ́ tí ó ti ọ̀dọ̀ àwọn ẹ̀mí èṣù wá.

2. Ẹnu àwọn àgàbàgebè eniyan ni ẹ̀kọ́ burúkú wọnyi yóo ti wá, àwọn tí wọn ń sọ̀rọ̀ èké; àwọn tí Satani ń darí ẹ̀rí-ọkàn wọn.

3. Irú wọn ni wọ́n ń sọ pé kí eniyan má ṣe gbeyawo. Wọ́n ní kí eniyan má ṣe jẹ àwọn oríṣìí oúnjẹ kan, bẹ́ẹ̀ sì ni Ọlọrun ni ó dá a pé kí àwọn onigbagbọ ati àwọn tí wọ́n mọ òtítọ́ máa jẹ ẹ́ pẹlu ọpẹ́.

4. Nítorí ohun gbogbo tí Ọlọrun dá ni ó dára. Kò sí ohun tí a gbọdọ̀ kọ̀ bí a bá gbà á pẹlu ọpẹ́,

5. nítorí ọ̀rọ̀ Ọlọrun ati adura ti sọ ọ́ di mímọ́.

6. Bí o bá ń fi irú ọ̀rọ̀ báyìí siwaju àwọn arakunrin, ìwọ yóo jẹ́ òjíṣẹ́ rere ti Kristi Jesu, tí a tọ́ dàgbà ninu ọ̀rọ̀ igbagbọ ati ẹ̀kọ́ rere tí ò ń tẹ̀lé.

7. Má jẹ́ kí á bá ọ ní ìdí ìtàn àgbọ́sọ tí kò wúlò ati àwọn ìtànkítàn tí àwọn ìyá arúgbó fẹ́ràn. Ṣe ara rẹ yẹ fún ìgbé-ayé eniyan Ọlọrun.

8. Eniyan a máa rí anfaani níwọ̀nba tí ó bá ń ṣe eré ìdárayá ti ara, ṣugbọn anfaani ti ẹ̀mí kò lópin; nítorí ó ní anfaani ní ayé yìí, ó tún fún eniyan ní anfaani ti ayé tí ń bọ̀.

9. Òdodo ọ̀rọ̀ nìyí, ó sì yẹ kí eniyan gbà á tọkàntọkàn.

10. Ìdí tí a fi ń ṣe làálàá nìyí, tí a sì ń jìjàkadì, nítorí a gbẹ́kẹ̀lé Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó jẹ́ Olùgbàlà gbogbo eniyan, pàápàá jùlọ ti àwọn onigbagbọ.

11. Àwọn nǹkan wọnyi ni kí o máa pa láṣẹ, kí o sì máa kọ́ àwọn eniyan.

Ka pipe ipin Timoti Kinni 4