Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 4:18-22 BIBELI MIMỌ (BM)

18. Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin.

19. Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi.

20. Erastu ti dúró ní Kọrinti. Mo fi Tirofimọsi sílẹ̀ ní Miletu pẹlu àìlera.

21. Sa ipá rẹ láti wá kí ó tó di àkókò òtútù.Yubulọsi kí ọ, ati Pudẹsi, Linọsi, Kilaudia ati gbogbo àwọn arakunrin.

22. Kí Oluwa wà pẹlu ẹ̀mí rẹ.Kí oore-ọ̀fẹ́ wà pẹlu gbogbo yín.

Ka pipe ipin Timoti Keji 4