Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 4:10-19 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Demasi ti fi mí sílẹ̀ nítorí ó fẹ́ràn nǹkan ayé yìí. Ó ti lọ sí Tẹsalonika. Kirẹsẹnsi ti lọ sí Galatia. Titu ti lọ sí Dalimatia.

11. Luku nìkan náà ni ó kù lọ́dọ̀ mi. Mú Maku lọ́wọ́ bí o bá ń bọ̀ nítorí ó wúlò fún mi bí iranṣẹ.

12. Mo ti rán Tukikọsi lọ sí Efesu.

13. Nígbà tí o bá ń bọ̀, bá mi mú agbádá tí mo fi sọ́dọ̀ Kapu ní Tiroasi bọ̀. Bá mi mú àwọn ìwé mi náà bọ̀, pataki jùlọ àwọn ìwé aláwọ mi.

14. Alẹkisanderu, alágbẹ̀dẹ bàbà fi ojú mi rí nǹkan! Kí Oluwa san ẹ̀san fún un gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ rẹ̀.

15. Kí ìwọ náà ṣọ́ra lọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí títa ni ó ń tako àwọn ohun tí à ń sọ.

16. Nígbà tí mo níláti jà fún ara mi ní ẹẹkinni, kò sí ẹni tí ó yọjú láti gbèjà mi: gbogbo wọn ni wọ́n fi mí sílẹ̀. Kí Ọlọrun má kà á sí wọn lọ́rùn.

17. Ṣugbọn Oluwa dúró tì mí, ó fún mi lágbára tí mo fi waasu ìyìn rere lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́, tí gbogbo àwọn tí kì í ṣe Juu fi gbọ́. Bẹ́ẹ̀ ni mo ṣe bọ́ lẹ́nu kinniun.

18. Oluwa yóo yọ mí kúrò ninu iṣẹ́ burúkú gbogbo, yóo sì gbà mí sinu ìjọba rẹ̀ ní ọ̀run. Tirẹ̀ ni ògo lae ati laelae. Amin.

19. Kí Pirisila ati Akuila ati ìdílé Onesiforosi.

Ka pipe ipin Timoti Keji 4