Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 3:10-17 BIBELI MIMỌ (BM)

10. Ṣugbọn ìwọ ní tìrẹ, o ti tẹ̀lé ẹ̀kọ́ mi, ati ọ̀nà ìgbé-ayé mi, ète mi, ati igbagbọ mi, sùúrù mi, ìfẹ́ mi ati ìfaradà mi,

11. ninu inúnibíni, ninu irú ìyà tí ó bá mi ní Antioku, ní Ikoniomu, ní Listira, ati oríṣìíríṣìí inúnibíni tí mo faradà. Oluwa ni ó yọ mí ninu gbogbo wọn.

12. Wọn yóo ṣe inúnibíni sí gbogbo ẹni tí ó bá fẹ́ gbé ìgbé-ayé olùfọkànsìn gẹ́gẹ́ bí onigbagbọ. Inúnibíni níláti dé sí wọn.

13. Ṣugbọn yóo túbọ̀ máa burú sí i ni fún àwọn eniyan burúkú ati àwọn ẹlẹ́tàn: wọn yóo máa tan eniyan jẹ, eniyan yóo sì máa tan àwọn náà jẹ.

14. Ṣugbọn, ìwọ ní tìrẹ, dúró gbọningbọnin ninu àwọn ohun tí o ti kọ́, tí ó sì dá ọ lójú. Ranti ọ̀dọ̀ àwọn ẹni tí o ti kọ́ wọn.

15. Nítorí láti ìgbà tí o ti wà ní ọmọde ni o ti mọ Ìwé Mímọ́, tí ó lè sọ ọ́ di ọlọ́gbọ́n, tí o fi lè ní ìgbàlà nípa igbagbọ ninu Kristi Jesu.

16. Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni ó ní ìmísí Ọlọrun, ó sì wúlò fún ẹ̀kọ́, fún ìbáwí, fún ìtọ́nisọ́nà, fún ìlànà nípa ìwà òdodo,

17. kí eniyan Ọlọrun lè jẹ́ ẹni tí ó pé, tí ó múra sílẹ̀ láti ṣe gbogbo iṣẹ́ rere.

Ka pipe ipin Timoti Keji 3