Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Timoti Keji 1:1-7 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun gẹ́gẹ́ bí ìlérí ìyè tí ó wà ninu Kristi Jesu, èmi ni mò ń kọ ìwé yìí–

2. Sí Timoti, àyànfẹ́ ọmọ mi.Kí oore-ọ̀fẹ́, àánú ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba, ati Kristi Jesu, Oluwa wa, wà pẹlu rẹ.

3. Nígbà tí mo bá ń ranti rẹ ninu adura mi tọ̀sán-tòru, èmi a máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun tí mò ń sìn pẹlu ẹ̀rí-ọkàn mímọ́, gẹ́gẹ́ bí àwọn baba-ńlá mi ti ṣe.

4. Nígbà tí mo bá ranti ẹkún tí o sun, a dàbí kí n tún rí ọ, kí ayọ̀ mi lè di kíkún.

5. Mo ranti igbagbọ rẹ tí kò lẹ́tàn, tí ó kọ́kọ́ wà ninu Loisi ìyá-ìyá rẹ, ati ninu Yunisi ìyá rẹ, tí ó sì dá mi lójú pé ó wà ninu ìwọ náà.

6. Ìdí nìyí tí mo fi ń rán ọ létí pé kí o máa rú ẹ̀bùn-ọ̀fẹ́ Ọlọrun sókè, tí a fi fún ọ nípa ọwọ́ mi tí mo gbé lé ọ lórí.

7. Nítorí kì í ṣe ẹ̀mí ojo ni Ọlọrun fún wa bíkòṣe ẹ̀mí agbára ati ti ìfẹ́ ati ti ìkóra-ẹni-níjàánu.

Ka pipe ipin Timoti Keji 1