Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Keji 3:11-18 BIBELI MIMỌ (BM)

11. Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri.

12. A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.

13. Ará, ẹ má ṣe jẹ́ kí rere su yín í ṣe.

14. Bí ẹnikẹ́ni kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ wa ninu ìwé yìí, ẹ wo irú ẹni bẹ́ẹ̀ dáradára. Ẹ má ṣe bá a da nǹkankan pọ̀, kí ó lè yí pada.

15. Ẹ má mú un lọ́tàá, ṣugbọn ẹ máa gbà á níyànjú bí onigbagbọ.

16. Kí Oluwa alaafia fúnrarẹ̀ fun yín ní alaafia nígbà gbogbo lọ́nà gbogbo. Kí Oluwa wà pẹlu gbogbo yín.

17. Èmi Paulu ni mò ń fi ọwọ́ ara mi pàápàá kọ ìwé yìí. Bí èmi ti máa ń kọ̀wé nìyí.

18. Kí oore-ọ̀fẹ́ Oluwa wa Jesu Kristi kí ó wà pẹlu gbogbo yín.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Keji 3