Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Keji 3:1-12 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Ní ìparí, ẹ̀yin ará, ẹ máa gbadura fún wa, pé kí ọ̀rọ̀ Oluwa lè máa gbilẹ̀, kí ògo rẹ̀ máa tàn sí i, àní gẹ́gẹ́ bí ó ti rí láàrin yín.

2. Kí ẹ tún máa gbadura pé kí Ọlọrun gbà wá lọ́wọ́ àwọn eniyan burúkú ati àwọn ìkà, nítorí kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó gbàgbọ́.

3. Ṣugbọn olódodo ni Oluwa, òun ni yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, tí yóo sì pa yín mọ́ kúrò ninu ibi gbogbo.

4. A ní ìdánilójú ninu Oluwa nípa yín pé àwọn ohun tí a ti sọ, tí ẹ sì ń ṣe, ni ẹ óo máa ṣe.

5. Oluwa yóo tọ́ ọkàn yín láti mọ ìfẹ́ Ọlọrun ati ohun tí Kristi faradà nítorí yín.

6. Ẹ̀yin ará, à ń pàṣẹ fun yín ní orúkọ Oluwa wa Jesu Kristi pé kí ẹ yẹra fún àwọn onigbagbọ tí wọn bá ń rìn ségesège, tí wọn kò tẹ̀lé ẹ̀kọ́ tí ẹ ti kọ́ lọ́dọ̀ wa.

7. Nítorí ẹ̀yin fúnra yín mọ bí ó ti yẹ kí ẹ ṣe àfarawé wa, nítorí a kò rìn ségesège nígbà tí a wà láàrin yín.

8. Bẹ́ẹ̀ ni a kò jẹ oúnjẹ ẹnikẹ́ni ninu yín lọ́fẹ̀ẹ́. Ṣugbọn ninu làálàá ati ìṣòro ni à ń ṣiṣẹ́ tọ̀sán-tòru, kí á má baà ni ẹnikẹ́ni ninu yín lára.

9. Kì í ṣe pé a kò ní ẹ̀tọ́ láti jẹun lọ́dọ̀ yín; ṣugbọn a kò ṣe bẹ́ẹ̀ kí á lè fi ara wa ṣe àpẹẹrẹ fun yín, kí ẹ lè fara wé wa.

10. Nítorí nígbà tí a wà lọ́dọ̀ yín, a pàṣẹ fun yín pé bí ẹnikẹ́ni bá kọ̀ tí kò ṣiṣẹ́, ẹ má jẹ́ kí ó jẹun.

11. Nítorí a gbọ́ pé àwọn kan ninu yín ń rìn ségesège, wọn kì í ṣiṣẹ́ rárá, ẹsẹ̀ ni wọ́n fi í máa wọ́lẹ̀ kiri.

12. A pàṣẹ fún irú àwọn bẹ́ẹ̀, a tún ń rọ̀ wọ́n ninu Oluwa Jesu Kristi pé kí wọ́n máa ṣiṣẹ́ wẹ́rẹ́wẹ́rẹ́ fún oúnjẹ ti ara wọn.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Keji 3