Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Keji 2:7-17 BIBELI MIMỌ (BM)

7. Nítorí nǹkan àṣírí kan tíí máa fa rúkèrúdò ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́, ṣugbọn ẹni tí ó ń ká a lọ́wọ́ kò wà, kò ì kúrò lọ́nà.

8. Nígbà tí ó bá kúrò lọ́nà tán ni Ọkunrin Burúkú nnì yóo wá farahàn. Ṣugbọn Oluwa Jesu yóo fi èémí ẹnu rẹ̀ pa á, yóo sọ ìfarahàn rẹ̀ di asán.

9. Nítorí Ẹni Burúkú yìí yóo farahàn pẹlu agbára Èṣù: yóo máa pidán, yóo ṣe iṣẹ́ àmì, yóo ṣe iṣẹ́ ìtànjẹ tí ó yani lẹ́nu.

10. Yóo fi ọ̀nà àrékérekè burúkú lóríṣìíríṣìí tan àwọn ẹni ègbé jẹ, nítorí wọn kò ní ìfẹ́ òtítọ́, tí wọn ìbá fi rí ìgbàlà.

11. Nítorí èyí, Ọlọrun rán agbára ìtànjẹ sí wọn, kí wọ́n lè gba èké gbọ́,

12. kí gbogbo àwọn tí kò gba òtítọ́ gbọ́ lè gba ìdálẹ́bi, àní, àwọn tí wọ́n ní inú dídùn sí ìwà ibi.

13. Ṣugbọn ó yẹ kí á máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun nítorí yín, ẹ̀yin ará, àyànfẹ́ Oluwa, nítorí Ọlọrun ti yàn yín láti ìbẹ̀rẹ̀ wá láti gbà yín là nípa Ẹ̀mí tí ó sọ yín di mímọ́, ati nípa gbígba òtítọ́ gbọ́.

14. Ọlọrun pè yín sí ipò yìí nípa iwaasu wa, kí ẹ lè jogún ògo Oluwa wa Jesu Kristi.

15. Nítorí náà, ẹ̀yin ará, ẹ dúró ṣinṣin, kí ẹ di àwọn ẹ̀kọ́ tí a fi le yín lọ́wọ́ mú, kì báà ṣe àwọn tí a kọ yín nípa ọ̀rọ̀ ẹnu tabi nípa ìwé tí à ń kọ si yín. Bẹ́ẹ̀ ni àwa náà gbà á.

16. Oluwa wa fúnrarẹ̀ ati Ọlọrun Baba wa, tí ó fẹ́ wa, tí ó fún wa ní ìtùnú ayérayé ati ìrètí rere nípa oore-ọ̀fẹ́,

17. yóo tù yín ninu, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀ ninu oríṣìíríṣìí iṣẹ́ ati ọ̀rọ̀ rere.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Keji 2