Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Tẹsalonika Keji 1:10-12 BIBELI MIMỌ (BM)

10. nígbà tí Oluwa bá dé ní ọjọ́ náà láti gba ògo lọ́dọ̀ àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀, nígbà tí gbogbo àwọn tí ó gbàgbọ́ yóo máa yẹ́ ẹ sí, nítorí wọ́n gba ẹ̀rí tí a jẹ́ fún wọn gbọ́.

11. Nítorí èyí ni a fi ń gbadura fun yín nígbà gbogbo, pé kí Ọlọrun wa lè kà yín yẹ fún ìpè tí ó pè yín, kí ó mú èrò gbogbo ṣẹ, kí ó sì fi agbára fun yín láti máa gbé ìgbé-ayé tí ó yẹ onigbagbọ;

12. kí ẹ lè yin orúkọ Oluwa wa Jesu lógo, kí òun náà sì yìn yín, gẹ́gẹ́ bí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun wa ati ti Oluwa Jesu Kristi.

Ka pipe ipin Tẹsalonika Keji 1