Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 9:23-33 BIBELI MIMỌ (BM)

23. Báyìí náà ni ó fi ògo ńlá rẹ̀ hàn pẹlu fún àwọn tí ó ṣàánú fún, àní fún àwa tí ó ti pèsè ọlá sílẹ̀ fún.

24. Àwa náà ni ó pè láti ààrin àwọn Juu ati láti ààrin àwọn tí kìí ṣe Juu pẹlu;

25. bí ó ti sọ ninu Ìwé Hosia pé,“Èmi yóo pe àwọn tí kì í ṣe eniyan mi ní ‘Eniyan mi.’N óo sì pe àwọn orílẹ̀-èdè tí n kò náání ní ‘Àyànfẹ́ mi.’

26. Ní ibìkan náà tí a ti sọ fún wọn rí pé,‘Ẹ kì í ṣe eniyan mi mọ́’ni a óo ti pè wọ́n níọmọ Ọlọrun alààyè.”

27. Aisaya náà kéde nípa Israẹli pé, “Bí àwọn ọmọ Israẹli tilẹ̀ pọ̀ bí iyanrìn òkun, sibẹ díẹ̀ péré ni a óo gbà là.

28. Nítorí ṣókí ati wéré wéré ni ìdájọ́ Ọlọrun yóo jẹ́ lórí ilẹ̀ ayé.”

29. Ṣiwaju eléyìí, Aisaya sọ bákan náà pé, “Bíkòṣe pé Oluwa alágbára jùlọ dá díẹ̀ sí ninu àwọn ọmọ wa ni, bíi Sodomu ni à bá rí, à bá sì dàbí Gomora.”

30. Kí ni èyí já sí? Ó já sí pé àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bìkítà rárá láti wá ojurere Ọlọrun, àwọn náà gan-an ni Ọlọrun wá dá láre, ó dá wọn láre nítorí wọ́n gbàgbọ́;

31. ṣugbọn Israẹli tí ó ń lépa òfin tí yóo mú wọn rí ìdáláre gbà níwájú Ọlọrun kò rí irú òfin bẹ́ẹ̀.

32. Nítorí kí ni wọn kò ṣe rí òfin náà? Ìdí ni pé, wọn kò wá ìdáláre níwájú Ọlọrun nípa igbagbọ, ṣugbọn wọ́n gbẹ́kẹ̀ lé iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Wọ́n bá kọsẹ̀ lórí òkúta ìkọsẹ̀,

33. bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Mo gbé òkúta kan kalẹ̀ ní Sionití yóo mú eniyan kọsẹ̀,tí yóo gbé eniyan ṣubú.Ṣugbọn ojú kò ní ti ẹni tí ó bá gbà á gbọ́.”

Ka pipe ipin Romu 9