Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 6:3-11 BIBELI MIMỌ (BM)

3. Àbí ẹ kò mọ̀ pé gbogbo àwa tí a ti rì bọmi lórúkọ Jesu a ti kú bí Jesu ti kú?

4. Bẹ́ẹ̀ ni wọ́n jọ sin wá pọ̀ nígbà tí wọ́n rì wá bọmi, tí wọ́n sọ wá di òkú, kí àwa náà lè máa gbé ìgbé-ayé titun gẹ́gẹ́ bí Ọlọrun baba ògo ti jí Kristi dìde kúrò ninu òkú.

5. Bí a bá sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu Jesu ninu ikú, a óo sọ wá di ọ̀kan náà pẹlu rẹ̀ ninu ajinde.

6. Ẹ jẹ́ kí òye yìí yé wa: a ti kan ẹni àtijọ́ tí àwọn eniyan mọ̀ wá sí mọ́ agbelebu pẹlu Jesu, kí ẹran-ara tí eniyan fi ń dẹ́ṣẹ̀ lè di òkú, kí á lè bọ́ lóko ẹrú ẹ̀ṣẹ̀.

7. Nítorí ẹni tí ó ti kú ti bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀.

8. Bí a bá jọ bá Jesu kú, a ní igbagbọ pé a óo jọ bá Jesu yè.

9. A mọ̀ pé Kristi tí a ti jí dìde kúrò ninu òkú, kò tún ní kú mọ́; ikú kò sì lè jọ̀gá lórí rẹ̀ mọ́.

10. Kíkú tí ó kú jẹ́ pé ó ti kú ikú tí ó níláti kú lẹ́ẹ̀kan; yíyè tí ó yè, ó yè fún ògo Ọlọrun.

11. Bákan náà ni kí ẹ ka ara yín bí ẹni tí ó ti kú ní ayé ẹ̀ṣẹ̀, tí ó tún wà láàyè pẹlu Ọlọrun ninu Kristi.

Ka pipe ipin Romu 6