Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 15:17-33 BIBELI MIMỌ (BM)

17. Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun.

18. N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi,

19. pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

20. Kì í ṣe àníyàn mi ni láti lọ waasu ìyìn rere níbi tí wọ́n bá ti gbọ́ orúkọ Kristi, kí n má baà kọ́lé lórí ìpìlẹ̀ tí ẹlòmíràn ti fi lélẹ̀.

21. Ṣugbọn àníyàn mi rí bí ọ̀rọ̀ tí ó wà ní àkọsílẹ̀ pé,“Àwọn ẹni tí kò gbọ́ nípa rẹ̀ rí, yóo rí i.Ọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ yóo yé àwọn tí kò gbúròó rẹ̀ rí.”

22. Ìdí nìyí tí mo fi ní ìdènà nígbà pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín.

23. Ṣugbọn nisinsinyii, mo ti parí iṣẹ́ mi ní gbogbo agbègbè yìí. Bí mo sì ti ní ìfẹ́ fún ọdún pupọ láti wá sọ́dọ̀ yín, mo lérò láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́tẹ̀ yìí.

24. N óo yà sọ́dọ̀ yín nígbà tí mo bá ń kọjá lọ sí Spania. Ìrètí mi ni láti ri yín, kí ẹ lè ràn mí lọ́wọ́, kí n lè débẹ̀, lẹ́yìn tí mo bá ti ní anfaani láti dúró lọ́dọ̀ yín fún ìgbà díẹ̀.

25. Ṣugbọn mò ń lọ sí Jerusalẹmu báyìí láti fi ẹ̀bùn tí wọ́n fi ranṣẹ sí àwọn onigbagbọ tí ó wà níbẹ̀ jíṣẹ́.

26. Nítorí àwọn ìjọ Masedonia ati ti Akaya ti fi inú dídùn ṣe ọrẹ fún àwọn aláìní ninu àwọn onigbagbọ tí ó wà ní Jerusalẹmu.

27. Wọ́n fi inú dídùn ṣe é, ó sì jẹ wọ́n lógún láti ṣe bẹ́ẹ̀. Nítorí bí àwọn tí kì í ṣe Juu ti pín ninu àwọn nǹkan ti ẹ̀mí ti àwọn onigbagbọ láti Jerusalẹmu, ó yẹ kí wọ́n kà á sí iṣẹ́ ìsìn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ pẹlu ohun ìní wọn.

28. Nítorí náà, nígbà tí mo bá parí ètò yìí, tí mo ti fi ọwọ́ ara mi fún wọn ní ohun tí a rí kójọ, n óo gba ọ̀dọ̀ yín kọjá sí Spania.

29. Mo mọ̀ pé, nígbà tí mo bá dé ọ̀dọ̀ yín, n óo wá pẹlu ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ibukun ti Kristi.

30. Ará, mo fi Oluwa wa Jesu Kristi ati ìfẹ́ ti Ẹ̀mí Mímọ́ bẹ̀ yín pé, kí ẹ máa fi ìtara bá mi gbadura sí Ọlọrun pé

31. kí á lè gbà mí lọ́wọ́ àwọn alaigbagbọ ní Judia, ati pé kí iṣẹ́ tí mò ń lọ ṣe ní Jerusalẹmu lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú àwọn onigbagbọ ibẹ̀.

32. Èyí yóo jẹ́ kí n fi ayọ̀ wá sọ́dọ̀ yín, bí Ọlọrun bá fẹ́, tí ọkàn mi yóo fi balẹ̀ nígbà tí mo bá wà lọ́dọ̀ yín.

33. Kí Ọlọrun alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo yín. Amin.

Ka pipe ipin Romu 15