Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 15:12-19 BIBELI MIMỌ (BM)

12. Aisaya tún sọ pé,“Gbòǹgbò kan yóo ti ìdílé Jese yọ,yóo yọ láti pàṣẹ fún àwọn orílẹ̀-èdè,nítorí lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìrètí àwọn orílẹ̀-èdè wà.”

13. Kí Ọlọrun tí ó ń fúnni ní ìrètí fi ayọ̀ tí ò kún ati alaafia fun yín nípa igbagbọ yín, kí ẹ lè máa dàgbà ninu ìrètí tí ẹ ní ninu Ẹ̀mí Mímọ́.

14. Ẹ̀yin ará, ó dá mi lójú pé ẹ̀yin fúnra yín kún fún inú rere, ẹ ní ìmọ̀ ohun gbogbo, ẹ mọ irú ìmọ̀ràn tí ẹ lè máa gba ara yín.

15. Sibẹ, mo ti fi ìgboyà tẹnumọ́ àwọn kókó ọ̀rọ̀ mélòó kan ninu ìwé yìí, láti ran yín létí nípa wọn. Mo ní ìgboyà láti sọ wọ́n fun yín nítorí oore-ọ̀fẹ́ tí Ọlọrun fún mi

16. láti jẹ́ iranṣẹ Kristi Jesu sí àwọn orílẹ̀-èdè tí kì í ṣe Juu. Mò ń ṣe iṣẹ́ alufaa láàrin àwọn orílẹ̀-èdè wọnyi nípa wiwaasu ìyìn rere Ọlọrun, kí wọ́n lè jẹ́ ọrẹ ìtẹ́wọ́gbà fún Ọlọrun, ọrẹ tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti yà sí mímọ́.

17. Nítorí náà, mo ní ohun tí mo lè fi ṣògo ninu Kristi Jesu, ninu iṣẹ́ tí mò ń ṣe fún Ọlọrun.

18. N kò jẹ́ sọ nǹkankan àfi àwọn nǹkan tí Kristi tọwọ́ mi ṣe, láti mú kí àwọn tí wọn kì í ṣe Juu lè gbọ́ràn sí Ọlọrun. Mo ṣe àwọn nǹkan wọnyi nípa ọ̀rọ̀ ati ìṣe mi,

19. pẹlu àwọn àmì ati iṣẹ́ ìyanu tí Ẹ̀mí fún mi lágbára láti ṣe. Àyọrísí èyí ni pé láti Jerusalẹmu títí dé Iliriku ni mo ti waasu ìyìn rere Kristi lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́.

Ka pipe ipin Romu 15