Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Romu 11:16-24 BIBELI MIMỌ (BM)

16. Bí a bá ya ìyẹ̀fun tí a kọ́kọ́ rí ninu ìkórè sí mímọ́, a ti ya burẹdi tí a fi ṣe sí mímọ́. Bí a bá ya gbòǹgbò igi sí mímọ́, a ti ya àwọn ẹ̀ka igi náà sí mímọ́.

17. A gé díẹ̀ ninu àwọn ẹ̀ka igi olifi inú oko kúrò, a wá lọ́ ẹ̀ka igi olifi inú tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́ dípò rẹ̀. Ẹ̀yin, tí ẹ kì í ṣe Juu, wá dàbí ẹ̀ka igi olifi tí ó lalẹ̀ hù ninu ìgbẹ́. Ẹ wá jọ ń rí oúnjẹ ati agbára láti ibìkan náà pẹlu àwọn Juu, tí ó jẹ́ igi olifi inú oko.

18. Nítorí náà, má ṣe fọ́nnu bí ẹni pé o sàn ju àwọn ẹ̀ka ti àkọ́kọ́ lọ. Tí o bá ń fọ́nnu, ranti pé kì í ṣe ìwọ ni ò ń gbé gbòǹgbò ró.

19. Ìwọ yóo wá wí pé, “Gígé ni a gé àwọn ẹ̀ka kúrò kí á lè fi mí rọ́pò wọn.”

20. Lóòótọ́ ni. A gé wọn kúrò nítorí wọn kò gbàgbọ́, nípa igbagbọ ni ìwọ náà fi wà ní ipò rẹ. Mú èrò ìgbéraga kúrò lọ́kàn rẹ, kí o sì ní ọkàn ìbẹ̀rù.

21. Nítorí bí Ọlọrun kò bá dá àwọn tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ sí, kò ní dá ìwọ náà sí.

22. Nítorí náà ṣe akiyesi ìyọ́nú Ọlọrun ati ìrorò rẹ̀. Ó rorò sí àwọn tí ó kùnà. Yóo yọ́nú sí ọ, tí o bá farabalẹ̀ gba ìyọ́nú rẹ̀, bí bẹ́ẹ̀ kọ́, yóo gé ìwọ náà kúrò pẹlu.

23. Àwọn Juu tí a gé kúrò yóo tún bọ́ sí ipò wọn pada, bí wọn bá kọ ọ̀nà aigbagbọ sílẹ̀. Ọlọrun lágbára láti tún lọ́ wọn pada sí ibi tí ó ti gé wọn.

24. Ìwọ tí ó jẹ́ bí ẹ̀ka igi olifi tí ó la ilẹ̀ hù ninu ìgbẹ́, tí a lọ́ mọ́ ara igi olifi inú oko, tí ẹ̀dá wọn yàtọ̀ sí ara wọn, báwo ni yóo ti rọrùn tó láti tún lọ́ àwọn tí ó jẹ́ ara igi olifi inú oko tẹ́lẹ̀ mọ́ ara igi tí a ti gé wọn kúrò!

Ka pipe ipin Romu 11