Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Kinni 5:5-14 BIBELI MIMỌ (BM)

5. Bákan náà, ẹ̀yin ọ̀dọ́, ẹ máa tẹríba fún àwọn àgbà. Gbogbo yín, ẹ gbé ọkàn ìrẹ̀lẹ̀ wọ̀, bí ẹ ti ń bá ara yín lò, nítorí,“Ọlọrun lòdì sí àwọn onigbeeraga,ṣugbọn a máa fi ojurere wo àwọn onírẹ̀lẹ̀.”

6. Nítorí náà, ẹ rẹ ara yín sílẹ̀ lábẹ́ ọwọ́ Ọlọrun tí ó lágbára, yóo gbe yín ga ní àkókò tí ó bá wọ̀.

7. Ẹ kó gbogbo ìpayà yín tọ̀ ọ́ lọ, nítorí ìtọ́jú yín jẹ ẹ́ lógún.

8. Ẹ ṣọ́ra. Ẹ dira yín gírí, Èṣù tíí ṣe ọ̀tá yín, ń rìn kiri bíi kinniun tí ń bú ramúramù, ó ń wá ẹni tí yóo pa jẹ.

9. Ẹ takò ó pẹlu igbagbọ tí ó dúró gbọningbọnin. Kí ẹ mọ̀ pé àwọn onigbagbọ ẹgbẹ́ yín ń jẹ irú ìyà kan náà níwọ̀n ìgbà tí wọ́n wà ninu ayé.

10. Ṣugbọn lẹ́yìn tí ẹ bá ti jìyà díẹ̀, Ọlọrun tí ó ní gbogbo oore-ọ̀fẹ́, òun tí ó pè yín sinu ògo rẹ̀ ayérayé nípasẹ̀ Kristi, yóo mu yín bọ̀ sípò, yóo fi ẹsẹ̀ yín múlẹ̀, yóo fun yín ní agbára, yóo sì tún fi ẹsẹ̀ ìgbé-ayé yín múlẹ̀.

11. Òun ni agbára wà fún laelae. Amin.

12. Silifanu ni ó bá mi kọ ìwé kúkúrú yìí si yín. Mo ka Silifanu yìí sí arakunrin tí ó ṣe é gbẹ́kẹ̀lé. Mò ń rọ̀ yín, mo tún ń jẹ́rìí pé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun tòótọ́ nìyí. Ẹ dúró lórí ohun tí mo kọ.

13. Ìjọ tí Ọlọrun yàn, ẹlẹgbẹ́ yín tí ó wà ní Babiloni ki yín. Bẹ́ẹ̀ náà ni Maku, ọmọ mi.

14. Ẹ fi ìfẹnukonu ìfẹ́ kí ara yín.Kí alaafia kí ó wà pẹlu gbogbo ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ ti Kristi.

Ka pipe ipin Peteru Kinni 5