Atijọ Majemu

Majẹmu Titun

Peteru Keji 1:1-13 BIBELI MIMỌ (BM)

1. Èmi, Simoni Peteru iranṣẹ ati aposteli Jesu Kristi, ni mò ń kọ ìwé yìí sí àwọn tí wọn ní irú anfaani tí a níláti gbàgbọ́ bíi tiwa, nípa òdodo Ọlọrun wa ati ti Olùgbàlà wa Jesu Kristi.

2. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia pọ̀ sí i fun yín nípa mímọ Ọlọrun ati Jesu Oluwa wa.

3. Nípa agbára Ọlọrun tí kì í ṣe ti eniyan, ó ti fún wa ní ohun gbogbo tí yóo jẹ́ kí á gbé irú ìgbé-ayé tí ó dára ati ti ìwà-bí-Ọlọrun, nípa mímọ ẹni tí ó fi ògo ati ọlá rẹ̀ pè wá.

4. Nípasẹ̀ èyí ni a ti gba àwọn ìlérí iyebíye tí ó tóbi jùlọ, tí ó fi jẹ́ pé ẹ ti di alábàápín ninu ìwà Ọlọrun, ẹ sì ti sá fún ìbàjẹ́ tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti mú wọ inú ayé.

5. Nítorí èyí, kí ẹ ní ìtara láti fi ìwà ọmọlúwàbí kún igbagbọ yín, kí ẹ sì fi ìmọ̀ kún ìwà ọmọlúwàbí.

6. Ẹ fi ìkóra-ẹni-níjàánu kún ìmọ̀, kí ẹ fi ìgboyà kún ìkóra-ẹni-níjàánu, kí ẹ sì fi ìfọkànsìn kún ìgboyà.

7. Ẹ fi ìṣoore fún àwọn onigbagbọ kún ìfọkànsìn, kí ẹ sì fi ìfẹ́ kún ìṣoore fún àwọn onigbagbọ.

8. Nítorí tí ẹ bá ní àwọn nǹkan wọnyi; tí wọn ń dàgbà ninu yín, ìgbé-ayé yín kò ní jẹ́ lásán tabi kí ó jẹ́ aláìléso ninu mímọ Jesu Kristi.

9. Afọ́jú ni ẹni tí kò bá ní àwọn nǹkan wọnyi, olúwarẹ̀ kò ríran jìnnà, kò sì lè ronú ẹ̀yìn-ọ̀la. Irú ẹni bẹ́ẹ̀ ti gbàgbé ìwẹ̀mọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀ àtijọ́.

10. Ẹ̀yin ará, ìdí rẹ̀ nìyí tí ẹ fi gbọdọ̀ túbọ̀ ní ìtara láti fi pípè tí a pè yín ati yíyàn tí a yàn yín hàn. Tí ẹ bá ń ṣe àwọn nǹkan wọnyi, ẹ kò ní kùnà.

11. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ óo ti ṣe ní ẹ̀tọ́ láti rìn gaara wọ ìjọba ayérayé ti Oluwa wa, ati Olùgbàlà Jesu Kristi.

12. Nítorí náà ni mo ṣe pinnu pé n óo máa ran yín létí gbogbo nǹkan wọnyi, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ẹ ti mọ̀ wọ́n, ẹ sì ti fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ ninu òtítọ́ tí ẹ ti mọ̀.

13. Nítorí mo kà á sí ẹ̀tọ́ mi, níwọ̀n ìgbà tí mo wà ninu àgọ́ ara yìí, láti ji yín ninu oorun nípa rírán yín létí.

Ka pipe ipin Peteru Keji 1